Jẹ́nẹ́sísì 42:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà tí Jákọ́bù mọ̀ pé ọkà wà ní Éjíbítì, ó wí fún àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin pé, “Èéṣe tí ẹ ń wo ara yín lásán?”

2. “Mo tí gbọ́ pé ọkà wà ní ilẹ̀ Éjíbítì. Ẹ sọ̀kalẹ̀ lọ sí ibẹ̀ kí ẹ sì rà wá fún wa, kí a má ba à kú.”

3. Nigbà náà ni mẹ́wàá nínú àwọn arákùnrin Jósẹ́fù sọ̀kalẹ̀ lọ sí Éjíbítì láti ra ọkà.

4. Ṣùgbọ́n Jákọ́bù kò rán Bẹ́ńjámínì àbúrò Jósẹ́fù lọ pẹ̀lú wọn nítorí ẹ̀rù ń bàá kí aburú má ba à ṣẹlẹ̀ síi.

Jẹ́nẹ́sísì 42