5. Nígbà tí Ísọ̀ sì ṣe àkíyèsí àwọn ìyàwó àti ọmọ Jákọ́bù, ó bèèrè lọ́wọ́ Jákọ́bù pé, “Ti tani àwọn wọ̀nyí?”Jákọ́bù sì fèsì wí pé, “Èyí ni àwọn ọmọ tí Ọlọ́run nínú àánú rẹ̀ ti fi fún ìránṣẹ́ rẹ.”
6. Nígbà náà ni àwọn ìránṣẹ́bìnrin àti àwọn ọmọ wọn súnmọ́ tòsí, wọ́n sì tẹríba.
7. Lẹ́yìn náà ni Líà àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú dé, wọ́n sì tún tẹríba. Ní ìkẹyìn ni Jósẹ́fù àti Rákélì dé, wọ́n sì tún tẹríba pẹ̀lú.
8. Ísọ̀ sì béèrè pé, “Kín ni èrò rẹ tí o fi to àwọn ọ̀wọ̀ọ̀wọ̀ tí mo pàdé wọ̀nyí?”Jákọ́bù dáhùn pé, “Kí n ba le rí ojúrere rẹ ni olúwa mi.”
9. Ṣùgbọ́n Ísọ̀ wí pé, “Tèmi ti tó mi, pa èyí tí o ní mọ́ fún ara rẹ.”
10. Jákọ́bù bẹ̀ ẹ́ wí pé, “Rárá bẹ́ẹ̀ kọ́, bí ó bá ṣe pé, mo rí ojú rere rẹ, jọ̀wọ́ gba wọ́n lọ́wọ́ mi. Bí mo ṣe rí ojú rẹ̀ yìí, ó dàbí wí pé mo rí ojú Ọlọ́run ni báyìí, tí inú un rẹ̀ ti dùn sí mi.
11. Jọ̀wọ́ gba àwọn ohun tí mo mú wá wọ̀nyí lọ́wọ́ mi. Nítorí Ọlọ́run ti fi oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ hàn sí mi, gbogbo ohun tí mo fẹ́ sì ni mo ní.” Nígbà tí Jákọ́bù sì rọ̀ ọ́ pé Ísọ̀ gbọdọ̀ gbà wọ́n, Ísọ̀ sì gbà á.
12. Nígbà náà ni Ísọ̀ wí pé, “Jẹ́ kí a máa lọ, n ó sìn ọ.”
13. Ṣùgbọ́n Jákọ́bù wí fún un pé, “Ṣe ìwọ náà ṣe àkíyèsí pé ọ̀pọ̀ nínú àwọn ọmọ wọ̀nyí kéré, àwọn màlúù àti àgùntàn pẹ̀lú sì ní àwọn ọmọ kéékèèké. Bí a bá dà wọ́n rìn jìnnà ju bí agbára wọn se mọ lọ, wọ́n lè kú.
14. Èmi bẹ̀ ọ́, máa lọ ṣíwájú ìránṣẹ́ rẹ, àwọn ó sì máa rọra bọ̀, títí èmi àti àwọn ọmọ yóò fi dé ọdọ̀ olúwa mi ní Ṣéírì.”