7. Pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìbànújẹ́ ni Jákọ́bù fi pín àwọn ènìyàn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ sí ìpín méjì, ó sì pín àwọn ẹran ọ̀sìn, agbo ẹran àti ràkúnmí bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.
8. Nítorí ó rò ó nínú rẹ̀ pé, “Bí Ísọ̀ bá kọjú ogun sí ìpín kan, ìpín kejì yóò sá àsálà.”
9. Nígbà náà ni Jákọ́bù gbàdúrà pe, “Ọlọ́run Ábúráhámù baba mi, àti Ọlọ́run Ísáákì baba mi, Olúwa tí ó wí fún mi pé, ‘Padà sí orílẹ̀-èdè rẹ àti sọ́dọ̀ àwọn ìbátan rẹ, Èmi yóò sì ṣe ọ́ ní rere,’
10. Èmi kò tilẹ̀ yẹ fún àánú àti òtítọ́ tí o ń fi hàn fún ìránṣẹ́ rẹ. Nítorí pé, kìkì ọ̀pá mi ni mo mu kúrò ni ilé kọjá Jọ́dánì yìí, ṣùgbọ́n nísin yìí, èmi ti di ẹgbẹ́ méjì.