Jẹ́nẹ́sísì 30:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà tí Rákélì rí i pe òun kò bímọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìlara sí Líà, arabìnrin rẹ̀, ó sì wí fún Jákọ́bù pé, “Fún mi lọmọ, bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, èmi ó kú”

2. Inú sì bí Jákọ́bù sí i, ó sì wí pé, “Èmi ha wà ní ipò Olúwa, ẹni tí ó mú ọ yàgàn bí?”

3. Nígbà náà ni Rákélì wí pé, “Bílíhà ìránṣẹ́bìnrin mi nìyìí, bá a lòpọ̀, kí ó ba à le bí ọmọ fún mi, kí èmi si le è tipaṣẹ̀ rẹ̀ ní ọmọ.”

4. Báyìí ni Rákélì fi Bílíhà fún Jákọ́bù ní aya, ó sì bá a lò pọ̀.

5. Bílíhà sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan fún Jákọ́bù.

6. Rákélì sì wí pé, “Ọlọ́run ti ṣe ìdájọ́ mi; ó sì ti gbọ́ ohún ẹ̀bẹ̀ mi, ó sì fún mi ni ọmọkùnrin kan.” Nítorí ìdí èyí ni ó ṣe pe orúkọ rẹ̀ ní Dánì.

7. Bílíhà, ọmọ ọ̀dọ̀ Rákélì sì tún lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kéjì fún Jákọ́bù.

8. Nígbà náà ni Rákélì wí pé, “Mo ti bá ẹ̀gbọ́n mi ja ìjàkadì ńlá, èmi sì ti borí.” Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Náfítalì.

9. Nígbà tí Líà sì ri pé òun ko tún lóyún mọ́, ó sì fi ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin, Ṣílípà fún Jákọ́bù bí aya.

10. Ṣílípà ọmọ ọ̀dọ̀ Líà sì bí ọmọkùnrin kan fún Jákọ́bù

Jẹ́nẹ́sísì 30