21. Olúwa sì dá ẹ̀wù awọ fún Ádámù àti aya rẹ̀, ó sì fi wọ̀ wọ́n.
22. Olúwa Ọlọ́run sì wí pé, “Ọkùnrin náà ti dàbí ọ̀kan lára wa, ó mọ rere àti búburú. A kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ó na ọwọ́ rẹ̀ kí ó mú lára èṣo igi ìyè kí ó sì jẹ, kí ó sì wà láàyè títí láéláé.”
23. Nítorí náà, Olúwa Ọlọ́run lé e kúrò nínú ọgbà Édẹ́nì láti lọ máa ro ilẹ̀ nínú èyí tí a ti mú un jáde wá.
24. Lẹ́yìn tí ó ti lé ènìyàn jáde tan, ó fi àwọn Kérúbù àti idà iná tí ó ń kọ mọ̀nàmọ̀nà ṣíwájú àti sẹ́yìn, sọ́ ọ̀nà tí ó lọ síbi igi ìyè, ní ìhà ìlà oòrún ọgbà Édẹ́nì.