Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ejò ṣáà ṣe alárékérekè ju àwọn ẹranko igbó yóòkù tí Olúwa Ọlọ́run dá lọ. Ó sọ fún obìnrin náà pé, “Ǹjẹ́ òtítọ́ há ni Ọlọ́run wí pé, ‘Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jẹ èṣo èyíkéyìí lára àwọn igi tí ó wà nínú ọgbà’?”

2. Obìnrin náà dá ejò lóhùn pé, “Àwá lè jẹ lára àwọn èṣo igi tí ó wà nínú ọgbà,

3. ṣùgbọ́n Ọlọ́run sọ pé, ‘Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jẹ lára èṣo igi tí ó wà láàrin ọgbà, ẹ kò sì gbọdọ̀ fi ọwọ́ kàn án, bí ẹ̀yin bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin yóò kú.’ ”

4. Ejò wí fún obìnrin náà pé, “Ẹ̀yin kì yóò kú ikúkíkú kan.”

5. “Nítorí Ọlọ́run mọ̀ wí pé, bí ẹ̀yin bá jẹ nínú rẹ̀, ojú yín yóò là, ẹ̀yin yóò sì dàbí Ọlọ́run, ẹ̀yin yóò sì mọ rere yàtọ̀ sí búburú.”

Jẹ́nẹ́sísì 3