Jẹ́nẹ́sísì 28:5-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Bẹ́ẹ̀ ni Ísáákì sì rán Jákọ́bù lọ. Ó sì lọ sí Padani-Árámù, lọ́dọ̀ Lábánì ọmọ Bétúélì, ará Árámíà, tí í ṣe arákùnrin Rèbékà ìyá Jákọ́bù àti Ísọ̀.

6. Nígbà tí Ísọ̀ gbọ pé, Ísáákì ti ṣúre fún Jákọ́bù, ó sì ti ran Jákọ́bù lọ sí Padani-Árámù láti fẹ́ aya níbẹ̀ àti pé nígbà tí ó ṣúre fún un, ó kìlọ̀ fun un pé, kò gbọdọ̀ fẹ́ nínú àwọn ọmọbìnrin Kénánì

7. àti pé, Jákọ́bù ti gbọ́ràn sí ìyá àti baba rẹ̀ lẹ́nu, ó sì ti lọ sí Padani-Árámù.

8. Nígbà náà ni Ísọ̀ mọ bí Ísáákì baba rẹ ti kórìíra àwọn ọmọbìnrin Kénánì tó.

9. Nítorí náà ó tọ Íṣímáélì lọ, ó sì fẹ́ Máhálátì, arábìnrin Nébájótù, ọmọbìnrin Ísímáélì tí í ṣe ọmọ Ábúráhámù. Ó fẹ́ ẹ, kún àwọn ìyàwó tí ó ti ní tẹ́lẹ̀

10. Jákọ́bù kúrò ní Bíáṣébà, ó sì kọrí sí ìlú Áránì.

11. Nígbà tí ó dé ibìkan, ó dúró ní òru náà nítorí tí ilẹ̀ ti ń sú, ó sì gbé òkúta kan ó fi ṣe ìrọ̀rí, ó sì sùn.

12. Ó sì lá àlá pé, a gbé àkàsọ̀ kan dúró ti ó fi ìdí lélẹ̀, orí rẹ̀ sì kan ọ̀run, àwọn ańgẹ́lì Ọlọ́run sì ń gòkè, wọ́n sì ń sọ̀kalẹ̀ lórí rẹ̀.

Jẹ́nẹ́sísì 28