Jẹ́nẹ́sísì 28:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nítorí náà Ísáákì pe Jákọ́bù, ó sì súre fún un, ó sì pàṣẹ fún un pé; “Ìwọ kò gbọdọ̀ fẹ́ aya láàrin àwọn ọmọbìnrin Kénánì.

2. Dípò bẹ́ẹ̀ lọ sí Padani-Árámù, sí ilé Bétúélì, baba ìyá rẹ, kí ìwọ kí ó sì fẹ́ aya fún ara rẹ nínú àwọn ọmọbìnrin Lábánì arákùnrin ìyá rẹ.

3. Kí Ọlọ́run Olódùmarè kí ó bùkún fún ọ, kí ó sì mú ọ bí sí i, kí ó sì mú ọ pọ̀ sí i ní iye títí tí ìwọ yóò di àgbájọ àwọn ènìyàn.

Jẹ́nẹ́sísì 28