Jẹ́nẹ́sísì 22:9-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Nígbà tí wọn sì dé ibi tí Ọlọ́run sọ fún Ábúráhámù, ó mọ pẹpẹ kan, ó sì to igiọ lé e lórí, ó sì di Ísáákì ọmọ rẹ̀, ó sì da dùbúlẹ̀ lórí pẹpẹ náà.

10. Ábúráhámù sì nawọ́ mú ọ̀bẹ, láti dúńbú ọmọ rẹ̀.

11. Ṣùgbọ́n ańgẹ́lì Olúwa ké sí i láti ọ̀run wí pé “Ábúráhámù! Ábúráhámù!”Ábúráhámù sì dáhùn pé, “Èmi nìyí.”

12. Ańgẹ́lì Olúwa sì wí pé, “Má ṣe fọwọ́ kan ọmọ náà, ìwọ kò sì gbọdọ̀ ṣe é ni ohun kan. Nísinsin yìí ni mo mọ̀ pé o bẹ̀rù Ọlọ́run, nítorí pé ìwọ kò fi ọmọ rẹ, àní, ọmọ rẹ kan soso dùn mi.”

13. Ábúráhámù sì gbójú sókè, ó sì rí àgbò kan tí ó fi ìwo há pàǹtírí, ó sì lọ mú un, ó sì fi rú ẹbọ ṣíṣun, dípò ọmọ rẹ̀.

14. Ábúráhámù sì pe orúkọ ibẹ̀ ni, Olúwa yóò pèṣè (Jìhófà Jirè). Bẹ́ẹ̀ ni a sì ń wí títí di òní olónìí pé, “Ní orí òkè Olúwa, ni a ó ti pèsè.”

15. Ańgẹ́lì Olúwa sì tún pe Ábúráhámù láti ọ̀run lẹ́ẹ̀kejì.

16. Ó sì wí pé, Olúwa wí pé, “Mo fi ara mi búra, níwọ̀n bí ìwọ ti ṣe èyí, tí ìwọ kò fi ọmọ rẹ, àní, ọmọ rẹ kan ṣoṣo dùn mí,

17. dájúdájú, Èmi yóò bùkún ọ, Èmi yóò sì mú kí ìran rẹ yìí kí ó pọ̀ bí i ìràwọ̀ ojú ọ̀run àti bí i yanrìn etí òkun. Irú ọmọ rẹ yóò sì gba ẹnu ibodè àwọn ọ̀ta wọn,

18. àti nípaṣẹ̀ irú ọmọ rẹ ni a ó ti bùkún fún gbogbo orílẹ̀ èdè ayé nítorí tí ìwọ gbọ́ràn sí mi lẹ̀nu”

19. Nígbà náà ni Ábúráhámù padà tọ àwọn ìrànṣẹ́ rẹ̀ lọ. Gbogbo wọn sì padà lọ sí Báá-Ṣébà Ábúráhámù sì dúró ní Báá-Ṣébà.

20. Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí ni a wí fún Ábúráhámù pé, “Mílíkà aya Náhórì bí àwọn ọmọkùnrin fún-un.

21. Úsì, àkọ́bí rẹ̀, Búsì arákùnri rẹ̀, Kémúélì (Baba Árámù).

Jẹ́nẹ́sísì 22