Jẹ́nẹ́sísì 22:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà tí ó ṣe, Ọlọ́run dán Ábúráhámù wò, ó pè é, ó sì wí pé, “Ábúráhámù.”Ábúráhámù sì dáhùn pé, “Èmi nìyí.”

2. Ọlọ́run sì wí pé, “Mú ọmọ rẹ, àní Ísáakì ọmọ rẹ kan ṣoṣo o nì, tí ìwọ fẹ́ràn, lọ sí ilẹ̀ Móráyà, kí o sì fi rúbọ ṣíṣun níbẹ̀ lórí ọ̀kan nínú àwọn òkè tí èmi yóò sọ fún ọ”

3. Ábúráhámù sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ó sì di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní gàárì, ó sì mú méjì nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti Ísáákì ọmọ rẹ̀, ó sì ṣe igi fún ẹbọ ṣíṣun, ó sì gbéra lọ sí ibi tí Ọlọ́run ti sọ fún-un.

4. Nígbà tí ó di ọjọ kẹ́ta, Ábúráhámù gbé ojú sókè, ó sì rí ibi tí ó ń lọ ní òkèrè,

5. Ó sì wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ̀yin, ẹ dúró níhìn-ín pẹ̀lú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, èmi àti ọmọ yìí yóò lọ sí ọ̀hún-un-nì láti sin Olúwa, a ó sì tún pada wá bá a yín.”

6. Ábúráhámù sì gbé igi ẹbọ ṣíṣun náà ru Ísáákì, òun fúnra rẹ̀ sì mú iná àti ọ̀bẹ. Bí àwọn méjèèjì ti ń lọ,

7. Ísáákì sì sọ fún Ábúráhámù baba rẹ̀ wí pé, “Baba mi.”Ábúráhámù sì da lóhùn pé, “Èmi nìyí ọmọ mi.”Ísáákì sì tún wí pé, “Wò ó iná àti igi nìyí, ṣùgbọ́n níbo ni ọ̀dọ́ àgùntàn fún ẹbọ sísun náà wà?”

8. Ábúráhámù sì dáhùn pé, “Ọmọ mi, Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ni yóò pèsè ọ̀dọ̀-àgùntàn fún ẹbọ sísun náà.” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn méjèèjì tẹ̀ṣíwájú nínú ìrìn-àjò wọn.

9. Nígbà tí wọn sì dé ibi tí Ọlọ́run sọ fún Ábúráhámù, ó mọ pẹpẹ kan, ó sì to igiọ lé e lórí, ó sì di Ísáákì ọmọ rẹ̀, ó sì da dùbúlẹ̀ lórí pẹpẹ náà.

10. Ábúráhámù sì nawọ́ mú ọ̀bẹ, láti dúńbú ọmọ rẹ̀.

Jẹ́nẹ́sísì 22