Jẹ́nẹ́sísì 17:6-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Èmi yóò mú ọ bí si lọ́pọ̀lọ́pọ̀, ọ̀pọ̀ orílẹ̀ èdè ni èmi yóò sì mú ti ara rẹ jáde wá, àwọn ọba pẹ̀lú yóò sì ti inú rẹ jáde.

7. Èmi yóò sì gbé májẹ̀mú mi kalẹ̀ láàrin èmi àti ìwọ, ní májẹ̀mú ayérayé àti láàrin irú ọmọ rẹ ní ìran-ìran wọn, láti máa ṣe Ọlọ́run rẹ àti ti irú ọmọ rẹ lẹ́yìn rẹ.

8. Gbogbo ilẹ̀ Kénánì níbi tí ìwọ ti ṣe àjèjì ni èmi yóò fi fún ọ àti ìran rẹ lẹ́yìn rẹ láéláé, Èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn.”

9. Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún Ábúráhámù pé, “Ìwọ máa pa májẹ̀mú mí mọ́, ìwọ àti irú ọmọ rẹ lẹ́yìn rẹ àti àwọn ìran tí ó ń bọ̀.

10. Èyí ni májẹ̀mú mi pẹ̀lú rẹ àti ìran rẹ lẹ́yìn rẹ, májẹ̀mú tí ẹ gbọdọ̀ pa mọ́. Gbogbo ọkùnrin yín ni a gbọdọ̀ kọ ní ilà.

11. Ẹ̀yin yóò kọ ara yín ní ilà, èyí ni yóò jẹ́ àmì májẹ̀mú láàrin wa.

12. Ní gbogbo ìran tí ń bọ̀ lẹ̀yìn, gbogbo ọkùnrin ni a gbọdọ̀ kọ ni ilà ní ọjọ́ kẹjọ tí a bí wọn, àti àwọn tí a bí ní ilé rẹ, tàbí tí a fi owó rà lọ́wọ́ àwọn àjèjì, àwọn tí kì í ṣe ọmọ rẹ̀. Èyí yóò sì jẹ́ májẹ̀mú láéláé tí yóò wà láàrin Èmi àti irú ọmọ rẹ.

13. Ìbá à ṣe ẹni tí a bí nínú ilé rẹ, tàbí ẹni tí fi owó rà, gbọdọ̀ kọ wọ́n ní ilà; májẹ̀mú mí lára yín yóò jẹ́ májẹ̀mú ayérayé.

14. Gbogbo ọmọkùnrin tí kò bá kọ ilà, tí a ko kọ ní ilà abẹ́, ni a ó gé kúrò láàrin àwọn ènìyàn rẹ̀, nítorí pé ó da májẹ̀mú mi”

15. Ọlọ́run wí fún Ábúráhámù pé, “Ní ti Ṣáráì, aya rẹ̀, ìwọ kì yóò pè é ní Ṣáráì bí kò ṣe Ṣárà.

16. Èmi yóò bùkún fún-un, Èmi yóò sì fun ọ ní ọmọkùnrin kan nípaṣẹ̀ rẹ̀. Èmi yóò bùkún-un, yóò sì di ìyá àwọn orílẹ̀ èdè, àwọn ọba àwọn orílẹ̀ èdè yóò sì ti ara rẹ̀ jáde wá.”

17. Ábúráhámù sì dojúbolẹ̀, ó rẹ́rìn-ín, ó sì wí fún ara rẹ̀ pé, “A ó ha bí ọmọ fún ẹni ọgọ́rùn-ún (100) ọdún? Ṣárà tí í ṣe ẹni àádọ́rùn-ún (90) ọdún yóò ha bímọ bí”.

Jẹ́nẹ́sísì 17