13. Ẹnìkan tí ó sá àsálà sì wá ròyìn fún Ábúrámù, ará Ébérù. Ábúrámù sá ti tẹ̀dó sí igbó igi Óákù tí ó jẹ́ ti Mámúrè ará Ámórì, arákùnrin Ésíkólì àti Ánérì: àwọn ẹni tí ó ń bá Ábúrámù ní àṣepọ̀.
14. Nígbà tí Ábúrámù gbọ́ wí pé, a di Lọ́tì ní ìgbékùn, o kó àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ tí a bí sí ilẹ́ rẹ̀ tí ó sì ti kọ́ ni ogun jíjà jáde, wọ́n jẹ́ okòó-lé-lọ́ọ̀dúnrún ó dín méjì ènìyàn (318), ó sì lépa wọn títí dé Dánì.
15. Ní ọ̀gànjọ́ òru, Ábúrámù pín àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sí méjì, ó sì kọlù wọ́n, ó sì ṣẹ́gun wọn, ó sì lé wọn títí dé Oba, ní àríwá Dámásíkù.
16. Gbogbo ìkógun ni ó rí gbà padà àti ọmọ arákùnrin rẹ̀, Lọ́tì pẹ̀lú ohun-ìní rẹ̀, àti àwọn obìnrin pẹ̀lú àwọn ènìyàn tó kù.
17. Nígbà tí Ábúrámù ti ṣẹ́gun Kedolaómérì àti àwọn ọba tí ó pẹ̀lú rẹ̀, ọba Ṣódómù lọ pàdé e rẹ̀ ní àfonífojì Ṣáfè (èyí tí ó túmọ̀ sí Àfonífojì ọba).
18. Mélíkísédékì ọba Ṣálẹ́mù (Jérúsálẹ́mù) sì mú oúnjẹ àti ọtí wáìnì jáde wá. Òun ni àlùfáà Ọlọ́run, ọ̀gá ògo.
19. Ó sì súre fún Ábúrámù wí pé,“Ìbùkún ni fún Ábúrámù láti ọ̀dọ̀Ọlọ́run ọ̀gá ògo tí ó dá ọ̀run òun ayé.
20. Ìbùkún sì ni fún Ọlọ́run ọ̀gá ògojùlọ tí ó fi àwọn ọ̀tá rẹ lé ọ lọ́wọ́.”Ábúrámù sì fún un ní ìdámẹ́wàá ohun gbogbo.
21. Ọba Ṣódómù sì wí fún Ábúrámù pé, “Kó àwọn ènìyàn mi fún mi, ṣùgbọ́n mú àwọn ẹrù fún ara rẹ.”
22. Ṣùgbọ́n Ábúrámù dá ọba Ṣódómù lóhùn pé, “Mo ti búra fún Olúwa, Ọlọ́run ọ̀gá ògo, tí ó dá ọ̀run àti ayé, mo sì ti gbọ́wọ́ sókè,
23. pé, èmi kì yóò mú ohunkóhun tí í ṣe tìrẹ se tèmi, ìbáà kéré bí orí abẹ́rẹ́, kí ìwọ kí ó má ba à wí pé, ‘Mo sọ Ábúrámù di ọlọ́rọ̀.’
24. Èmi kì yóò gba ohunkóhun yàtọ̀ sí ohun tí àwọn ọkùnrin mi ti jẹ́, ṣùgbọ́n fi ìpín fún àwọn ọkùnrin tí ó bá mi lọ, Ánérì, Ésíkólì àti Mámúrè. Jẹ́ kí wọn kí ó gba ìpín wọn.”