Jẹ́nẹ́sísì 12:10-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Ìyàn kan sì mú ní ilẹ̀ náà, Ábúrámù sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí Éjíbítì láti ṣe àtìpó níbẹ̀ fún ìgbà díẹ̀, nítorí ìyàn náà mú gidigidi.

11. Bí ó ti ku díẹ̀ kí ó wọ Éjíbítì, ó wí fún Ṣáráì, aya rẹ̀ pé, “Mo mọ̀ pé arẹwà obìnrin ni ìwọ,

12. nígbà tí àwọn ara Éjíbítì bá rí ọ, wọn yóò wí pé, ‘Aya rẹ̀ nìyí.’ Wọn yóò si pa mí, ṣùgbọ́n wọn yóò dá ọ sí.

13. Nítorí náà, sọ pé, arábìnrin mi ni ìwọ, wọn yóò sì ṣe mí dáradára, a ó sì dá ẹ̀mí mi sí nítorí tìrẹ.”

14. Nígbà tí Ábúrámù dé Éjíbítì, àwọn ará Éjíbítì ri i pé aya rẹ̀ rẹwà gidigidi.

15. Nígbà tí àwọn ìjòyè Fáráò sì rí i, wọ́n ròyìn rẹ̀ níwájú u Fáráò, Wọ́n sì mú un lọ sí ààfin,

16. Ó sì kẹ́ Ábúrámù dáradára nítorí Ṣáráì, Ábúrámù sì ní àgùntàn àti màlúù, akọ àti abo, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin, pẹ̀lú u ràkunmí.

17. Olúwa sì rán àjàkálẹ̀-àrùn búburú sí Fáráò àti ilé rẹ̀, nítorí Sáráì aya Ábúrámù.

Jẹ́nẹ́sísì 12