Jákọ́bù 1:15-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Ǹjẹ́, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ nígbà tí ó bá lóyún a bí ẹ̀ṣẹ̀, àti ẹ̀ṣẹ̀ náà nígbà tí ó bá dàgbà tán a bí ikú.

16. Kí a má ṣe tàn yín jẹ, ẹ̀yin ará mi olùfẹ́.

17. Gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ẹ̀bùn pípé láti òkè ni ó ti wá, ó sì sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ baba ìmọ́lẹ̀ wá, lọ́dọ̀ ẹni tí kò lè yípadà gẹ́gẹ́ bí òjìji àyídà.

18. Ó pinnu láti fi ọ̀rọ̀ òtítọ́ bí wa kí àwa kí ó le jẹ́ àkọ́so nínú ohun gbogbo tí ó dá.

19. Kí ẹmọ èyí, ẹ̀yin ara mi olùfẹ́; jẹ́ kí olúkúlùkù ènìyàn kí ó máa yára láti gbọ́, kí ó lọ́ra láti fọhùn kí ó si lọ́ra láti bínú;

20. Nítorí ìbínú ènìyàn kì í ṣiṣẹ́ òdodo irú èyí tí Ọlọ́run ń fẹ́.

21. Nítorí náà, ẹ lépa láti borí gbogbo èérí àti ìwà búburútí ó gbilẹ̀ yíka, kí ẹ sì fi ọkàn tútù gba ọ̀rọ̀ náà tí a gbìn, tí ó lè gba ọkàn yín là.

22. Ẹ maa kan jẹ́ olùgbọ́ ọ̀rà náà lásán, kí ẹ má baà tipa èyí tan ara yín jẹ́. Ẹ ṣse ohun tí ó sọ.

23. Nítorí bí ẹnikẹ́ni bá jẹ́ olùgbọ́ ọ̀rọ̀ náà tí kò sì jẹ́ olùṣe, òun dàbí ọkùnrin tí ó ń ṣàkíyèsí ojú ara rẹ̀ nínú díńgí

24. Nítorí, lẹ́yìn tí ó bá ti sàkíyèsí ara rẹ̀, tí ó sì bá tirẹ̀ lọ, lójú kan náà òun sì gbàgbé bí òun ti rí.

25. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń wo inú òfin pípé, òfin òmìnira ni, tí ó sì dúró nínú rẹ̀, tí òun kò sì jẹ́ olùgbọ́ tí ń gbàgbé bí kò ṣe olùṣe rẹ̀, òun yóò jẹ́ alábùkún nínú iṣẹ́ rẹ̀.

26. Bí ẹnikẹ́ni bá rò pé òun ń sin Ọlọ́run nígbà tí kò kó ahọ́n rẹ̀ ní ìjánu, ó ń tan ọkàn ara rẹ̀ jẹ, ìsìn rẹ̀ sì jẹ́ asán.

27. Ìsìn mímọ́ àti aláìléèérí níwájú Ọlọ́run àti baba ni èyí, láti máa bojú tó àwọn aláìní-baba àti àwọn opó nínú ìpọ́njú wọn, àti láti pa ara rẹ̀ mọ́ láì lábàwọ́n kúrò nínú ayé.

Jákọ́bù 1