Ísíkẹ́lì 46:21-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. Ó sì mú mi lọ sí ìta àgbàlá, ó sì mú mi yí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rẹ̀ ká, mo sì ri àgbàlá mìíràn ní igun kọ̀ọ̀kan.

22. Ní ìgun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ìta àgbàlá tí ó pẹnupọ̀, ogójì ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn àti ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ní fífẹ̀; àgbàlá kọ̀ọ̀kan ni igun kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìwọ̀n kan náà.

23. Ní agbègbè inú ikọ̀ọ̀kan nínú àgbàlá náà ni ọwọ́ ilẹ̀ kan wà yíká wọn, a sì ṣe ibi ìdáná si abẹ́ ọwọ́ náà yípo.

24. Ó sì wí fún mi pé, “Ìwọ̀nyí ni àwọn ilé ìdáná níbi tí o ń ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ nínú tẹ́ḿpìlì yóò ti ṣe ẹbọ fún àwọn ènìyàn.”

Ísíkẹ́lì 46