5. Páṣíà, Kúsì àti Pútì yóò wà pẹ̀lú wọn, gbogbo wọn yóò wà pẹ̀lú asà àti ìsíborí wọn
6. Gómérì náà pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀, àti Bẹti-Tógárímà láti jìnnàjìnnà àríwá pẹ̀lú gbogbo àwọn ọ̀wọ́ ogun rẹ̀-ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè pẹ̀lú rẹ̀.
7. “ ‘Múra sílẹ̀, múra tán, kí ìwọ àti gbogbo ìjọ náà péjọpọ̀ pẹ̀lú rẹ, kí o sì pàṣẹ fún wọn.
8. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́, àwa yóò pè ọ́ fún àwọn ohun èlò ogun. Ní àwọn ọdún ọjọ́ iwájú ìwọ yóò dóti ilẹ̀ tí a ti gbà nígbà ogun, tí àwọn ènìyàn wọn kórajọ pọ̀ láti ọ̀pọ̀ orílẹ̀ èdè sí àwọn òkè gíga ti Ísírẹ́lì, tí ó ti di ahoro fún ìgbà pípẹ́. A ti mú wọn jáde láti ọ̀dọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè, nísínsínyìí gbogbo wọn ń gbé ní àìléwu.
9. Ìwọ àti ọ̀wọ́ ogun rẹ àti ọ̀pọ̀ orílẹ̀ èdè pẹ̀lú rẹ yóò gòkè, ẹ̀yin yóò tẹ̀ṣíwájú bí ìjì; ìwọ yóò dàbí ìkùùkuu tí ó bo ìlẹ̀ mọ́lẹ̀.
10. “ ‘Èyí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Ní ọjọ́ náà èrò kan yóò wá ṣọ́kan rẹ, ìwọ yóò sì pète ìlànà búbúru.