1. Ọrọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá:
2. “Ọmọ ènìyàn, kọ ojú rẹ sí Gógì, ti ilẹ̀ Mágógì; olórí Roṣi, Méṣékì, àti Túbálì ṣọtẹ́lẹ̀ ní ìlòdì sí i
3. kí ó sì wí pé: ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Èmi lòdì sí ọ, Ìwọ Gógì, olórí ọmọ Aládé Méṣékì àti Túbálì.
4. Èmi yóò yí ọ kiri, èmi yóò sì fi ìwọ̀ kọ́ ọ ní ẹnu, èmi yóò sì fà ọ́ jáde pẹ̀lú gbogbo ọmọ ogun rẹ, àwọn ẹṣin àti àwọn agẹsinjagun nínú ìhámọ́ra, àti ìpéjọ ńlá pẹ̀lú asà ogun ńlá àti kéékèèkéé, gbogbo wọn ń fi idà wọn.
5. Páṣíà, Kúsì àti Pútì yóò wà pẹ̀lú wọn, gbogbo wọn yóò wà pẹ̀lú asà àti ìsíborí wọn
6. Gómérì náà pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀, àti Bẹti-Tógárímà láti jìnnàjìnnà àríwá pẹ̀lú gbogbo àwọn ọ̀wọ́ ogun rẹ̀-ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè pẹ̀lú rẹ̀.
7. “ ‘Múra sílẹ̀, múra tán, kí ìwọ àti gbogbo ìjọ náà péjọpọ̀ pẹ̀lú rẹ, kí o sì pàṣẹ fún wọn.