Ísíkẹ́lì 34:19-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Ṣé dandan ni kí agbo ẹran mi jẹ́ koríko tí ẹ ti tẹ̀ mọ́lẹ̀, kí wọn sì mú omi tí wọ́n ti fi ẹsẹ̀ wọn sọ di ẹrẹ̀?

20. “ ‘Nítorí náà, èyí yìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí fún wọn: Wòó, èmi fúnra mi yóò ṣe ìdájọ́ láàárin àgùntàn tí ó sanra àti èyí tí ó rù.

21. Nítorí ti ìwọ sún síwájú pẹ̀lú ìhà àti èjìká, tí ìwọ sì kan aláìlágbára àgùntàn pẹ̀lú ìwo rẹ títí ìwọ fi lé wọn lọ,

Ísíkẹ́lì 34