Ísíkẹ́lì 34:11-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. “ ‘Nítorí èyí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Èmi fúnra mi yóò wá àgùntàn mi kiri, èmi yóò sì ṣe àwárí wọn.

12. Gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn ṣe fojú tó agbo ẹran rẹ̀ tí ó fọ́n ká nígbà tí ó wà pẹ̀lú wọn, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò se fojú tó àgùntàn mi. Èmi yóò gbá wọn kúrò ni gbogbo ibi tí wọ́n fọ́n ká sí ni ọjọ ìkúukùu àti òkùnkùn.

13. Èmi yóò mú wọn jáde kúrò ní àwọn orílẹ̀ èdè, èmi yóò sì kó wọn jọ láti inú àwọn ìlú, èmi yóò sì mú wọn wá sí ilẹ ara wọn. Èmi yóò mú wọn jẹ ni orí àwọn òkè gíga Ísírẹ́lì, ni àárin àwọn òkè àti ní gbogbo ibùdó ilẹ̀ náà.

14. Èmi yóò ṣe ìtọ́jú wọn ní pápá oko tútù dáradára, àní orí àwọn òkè gíga ti Ísírẹ́lì ni yóò jẹ́ ilẹ̀ ìjẹ koríko wọ́n. Níbẹ̀ wọn yóò dùbúlẹ̀ ní ilẹ ìjẹ koríko dídára, níbẹ̀ wọn yóò jẹun ní pápá oko tútù tí ó dara ní orí òkè ti Ísírẹ́lì.

15. Èmi fúnra mi yóò darí àgùntàn mi, èmi yóò mú wọn dùbúlẹ̀, ni Olúwa Ọlọ́run wí.

16. Èmi yóò ṣe àwárí àwọn tí ó nú, èmi yóò mú àwọn tí ó ń rin ìrìn àrè kiri padà. Èmi yóò di ọgbẹ́ àwọn tí ó farapa, èmi yóò sì fún àwọn aláìlágbára ni okun, ṣùgbọ́n àwọn tí ó sanra tí ó sì ni agbára ní èmi yóò parun. Èmi yóò ṣe olùsọ́ àwọn agbo ẹran náà pẹ̀lú òdodo.

17. “ ‘Ní tìrẹ, agbo ẹran mi, èyí yìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Èmi yóò ṣe ìdájọ́ láàrin àgùntàn kan àti òmíràn, àti láàrin àgbò àti ewúrẹ́.

18. Ṣé oúnjẹ jíjẹ ní pápá oko tútù dídára kò tó yín! Ṣé ó jẹ́ dandan fún ọ láti fi ẹsẹ̀ tẹ pápá oko tútù rẹ tí ó kù? Ṣé omi tí ó tòrò kò tó fún yín ní mímu? Ṣe dandan ni kí ó fi ẹrẹ̀ yí ẹsẹ̀ yín?

19. Ṣé dandan ni kí agbo ẹran mi jẹ́ koríko tí ẹ ti tẹ̀ mọ́lẹ̀, kí wọn sì mú omi tí wọ́n ti fi ẹsẹ̀ wọn sọ di ẹrẹ̀?

20. “ ‘Nítorí náà, èyí yìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí fún wọn: Wòó, èmi fúnra mi yóò ṣe ìdájọ́ láàárin àgùntàn tí ó sanra àti èyí tí ó rù.

21. Nítorí ti ìwọ sún síwájú pẹ̀lú ìhà àti èjìká, tí ìwọ sì kan aláìlágbára àgùntàn pẹ̀lú ìwo rẹ títí ìwọ fi lé wọn lọ,

22. Èmi yóò gba agbo ẹran mi là, a kì yóò sì kò wọ́n tì mọ́. Èmi yóò ṣe ìdájọ́ láàrin àgùntàn kan àti òmíràn.

Ísíkẹ́lì 34