Ísíkẹ́lì 33:18-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Bí olódodo ènìyàn ba yípadà kúrò nínú òdodo rẹ̀, tí o sì ṣe búburú, òun yóò kú nítorí rẹ̀.

19. Bí ènìyàn búburú bá yípadà kúrò nínú búburú rẹ̀, tí ó sì ṣe èyí tí ó tọ́ àti èyí tí ó yẹ, òun yóò yè nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀.

20. Ṣíbẹ̀, ilé Ísírẹ́lì ìwọ wí pé, ‘ọ̀nà Olúwa ki i ṣe òtítọ́.’ Ṣùgbọ́n èmi yóò ṣe ìdájọ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ̀ ṣe rí.”

21. Ní ọjọ́ karùn ún oṣù kẹ́wàá, ọdún kejìlá ìkólọ wa, ọkùnrin kan tí ó sá kúrò ni Jerúsálẹ́mù wá sọ́dọ̀ mi, ó sì wí pé, “Ìlú ńlá náà ti ṣubú!”

22. Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ tí ó ku ọ̀la tí ẹni tí ó sálọ náà yóò dé, ọwọ́ Olúwa sì níbẹ lára mi, o sì ya ẹnu mi ki ọkùnrin náà tó wá sọ́dọ̀ mi sílẹ̀ èmi kò sì lè dákẹ́ mọ́.

23. Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá:

24. “Ọmọ ènìyàn, àwọn ènìyàn tí ó ń gbé nínú ìparun ní ilẹ Ísírẹ́lì ń wí pé, ‘Ábúráhámù jẹ́ ọkùnrin kan, síbẹ̀ o gba ilẹ̀ ìní náà. Ṣùgbọ́n àwa pọ̀: Lóòótọ́ a ti fi ilẹ̀ náà fún wa gẹ́gẹ́ bí ìní wa.’

25. Nítorí náà sọ fún wọn pé, ‘Èyí yìí ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Níwọ̀n ìgbà tí ẹ̀yin jẹ ẹ̀ran pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ ni inú rẹ̀, tí ẹ̀yin sì wó àwọn ère yín, tí ẹ sì ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, Ẹ̀yin yóò ha gba ilẹ̀ náà?

26. Ẹ̀yin gbẹ́kẹ̀lé idà yín, ẹ̀yin ṣe nǹkan ìríra, ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú yín baa obìnrin aládúgbò rẹ̀ jẹ́. Ẹ̀yin yóò ha gba ilẹ̀ náà?’

27. “Sọ èyí fún wọn: ‘Èyí yìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Bí mo ti wà láààyè, àwọn tí ó kúrò nínú ìparun yóò ti ipa idà ṣubú, àwọn tí ẹranko búburú yóò pajẹ, àwọn tí ó sì wà ní ilé ìsọ àti inú ihò òkúta ni àjàkálẹ̀-àrùn yóò pa.

Ísíkẹ́lì 33