5. Kúṣì àti Pútì, Lídíà àti gbogbo Árábù, Líbíyà àti àwọn ènìyàn ilẹ̀ ìlérí yóò ṣubú nípa idà papọ̀ pẹ̀lú Éjíbítì.
6. “ ‘Èyí yìí ní Olúwa wí:“ ‘Àwọn alejò Éjíbítì yóò ṣubúagbára ìgbéraga rẹ yóò kùnàláti Mígídólì títí dé Ásúwánìwọn yóò ti ipa idà ṣubú láàárin rẹ;ní Olúwa Ọlọ́run wí:
7. Wọn yóò sì wàlára àwọn ilẹ̀ tí ó di ahoro,ìlú rẹ yóò sì wàní ara àwọn ìlú tí ó di ahoro.