16. “ ‘Árámù ṣòwò pẹ̀lú nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ òwò rẹ̀; wọn ṣe ìpààrọ̀ òkúta iyebíye, òwú elésèé àlùkò, iṣẹ́ ọ̀nà tí a fi abẹ́rẹ́ ṣe, asọ ọ̀gbọ̀ dáradára, ìlẹ̀kẹ̀ iyùn pupa fún ọjà títà rẹ.
17. “ ‘Júdà àti Ísírẹ́lì, àwọn ni oníṣòwò rẹ; wọn ṣe ìpààrọ̀ ọkà, Mínnítì, àkàrà àdídùn; pannági, oyin, epo àti ìpara olóòórùn dídùn ni wọ́n fi ná ọjà rẹ.
18. “ ‘Dámásíkù, ni oníṣòwò rẹ, nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ọjà tí ó ṣe àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀; ní ti ọtí wáìnì tí Helíbónì, àti irun àgùntàn funfun.
19. “ ‘Àwọn ará Dánì àti Gíríkì láti Úsálì ra ọjà títà rẹ; irin dídán, káṣíà ati kálámù ni àwọn ohun pàsípààrọ̀ ní ọjà rẹ.
20. “ ‘Dédánì ni oníṣòwò rẹ ní aṣọ ìjókòó-lẹ́sin fún ẹṣin-gígùn.
21. “ ‘Àwọn ará Árábù àti gbogbo àwọn ọmọ aládé Kédárì àwọn ni àwọn onibárà rẹ: ní ti ọ̀dọ́ àgùntàn, àgbò àti ewúrẹ́, nínú ìwọ̀nyí ni wọ́n ti jẹ́ oníbárà rẹ.