5. “Óhólà ń ṣe asẹ́wó nígbà tí ó sì jẹ́ tèmi; Ó sì ṣe ìfẹ́kúfẹ́ sí àwọn olólùfẹ̀ rẹ̀, àwọn jagunjagun ará Ásíríà.
6. Aṣọ aláró ni a fi wọ̀ wọ́n, àwọn gómìnà àti àwọn balógun, gbogbo wọn jẹ́ ọ̀dọ́mọkùnrin arẹwà àwọn tí ń gun ẹsin.
7. O fi ara rẹ̀ fún gbajúmọ̀ ọkùnrin Ásíríà gẹ́gẹ́ bí pansága obìnrin, o fi òrìsà gbogbo àwọn tí ó ní ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí i sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́,
8. kò fi ìwa aṣẹ́wó tí ó ti bẹ̀rẹ̀, ni Éjíbítì sílẹ̀, ní ìgbà èwe rẹ̀ àwọn ọkùnrin n bá a sùn, wọn fi ọwọ́ pa àyà èwe rẹ̀ lára wọn sì ń ṣe ìfẹ́kúùfẹ́ sí i.
9. “Nítorí náà mo fi i sílẹ̀ fún àwọn olólùfẹ́ rẹ̀, ará Ásíríà, tí ó ní ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí i.
10. Wọ́n bọ́ ọ sí ìhòòhò, wọ́n sì gba àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin rẹ̀ wọn sì pá wọn pẹ̀lú idà. Ó di ẹni ìfisọ̀rọ̀ sọ láàrin àwọn obìnrin wọ́n sì fi ìyà jẹ ẹ́.