Ísíkẹ́lì 19:12-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Ṣùgbọ́n a hú àjàrà yìí pẹ̀lú ìbínú,á sì wo o lulẹ̀, afẹ́fẹ́ láti ìlà oorùn sì mú koko,wọ́n sọ ọ́ di aláìléso,àwọn ẹka rẹ̀ tó lágbára tẹ́lẹ̀ sì rọ wọ́n sì jó wọn.

13. Báyìí, a tún ún gbìn sínú aṣálẹ̀ ni ilẹ̀ gbígbẹ àti ilẹ̀ tó ń pọ̀ǹgbẹ omi.

14. Iná sì jáde láti ọ̀kan lára ẹ̀ka rẹ̀ ó sì pa ẹ̀ka àti èso rẹ̀ run,débi pé kò sí ẹ̀ka tó lágbára lórí rẹ̀ mọ́; èyí to ṣe e fi ṣe ọ̀pá fún olórí mọ́.’Èyí ni orin ọ̀fọ̀ a o sì máa lo bí orin ọ̀fọ̀.”

Ísíkẹ́lì 19