Ísíkẹ́lì 19:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. “Kọ orin ọ̀fọ̀ nítorí àwọn ọmọ aládé Ísírẹ́lì

2. wí pé:“ ‘Èwo nínú abo kìnnìnu ni ìyá rẹ̀ ní àárin àwọn kìnnìún yóòkù?Ó sùn ní àárin àwọn ọ̀dọ́ kìnnìún ó sì ń tọ́jú àwọn ọmọ rẹ̀.

3. Ó sì tọ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀ dàgbà, ó sì di kìnnìún tó ní agbára,ó kọ́ ọ láti sọdẹ, ó sì ń pa àwọn ènìyàn jẹ.

4. Àwọn orílẹ̀ èdè gbọ́ nípa rẹ̀,wọ́n sì fi ẹ̀wọ̀n mú un nínú ààfin wọn.Wọn fi ẹ̀wọ̀n mu nu lọ sí ilẹ̀ Éjíbítì.

5. “ ‘Nígbà tí abo kìnìún yìí rí pé ìrètí rẹ̀ sì já sí asán,ó mú ọmọ rẹ̀ mìíràn ó sì tún tọ́ ọ dàgbà di kìnnìún tó ní agbára.

Ísíkẹ́lì 19