Ísíkẹ́lì 18:8-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Kò yá ènìyàn ni owó ẹ̀dá tàbí kò gba èlétó pọ̀jù. Ó yọ ọwọ́ rẹ̀ kúrò nínúìwà ẹ̀ṣẹ̀, ó sì ń ṣe ìdájọ́ àìṣègbèláàrin ọkùnrin kan àti èkejì rẹ̀.

9. Tí ó ń tẹ̀lé àsẹ mi,tí ó sì ń pa òfin mi mọ́ lotítọ́ àti lódodo.Ó jẹ́ olódodo,yóò yè nítòótọ́,ní Olúwa Ọlọ́run wí.

10. “Bí ó bá bi ọmọkùnrin, oniwà ipá, tó ń jalè, tó tún ń pànìyàn tó sì ń ṣe gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí sí arákùnrin rẹ̀

11. (bó tilẹ̀ jẹ́ pé baba rẹ kò se irú rẹ̀):“Ó ń jẹun lojúbọ lórí òkè gíga,o ba ìyàwó aládùúgbò rẹ̀ jẹ́.

12. Ó ni àwọn talákà àti aláìní lára,ó ń fipá jalè, kì í dá padà gẹ́gẹ́ bí ìlérí,o gbójú sókè sí òrìṣà,ó sì ń ṣe ohun ìríra.

Ísíkẹ́lì 18