44. “ ‘Gbogbo àwọn to ń pòwe, ni yóò máa pòwe yìí mọ́ ọ pé: “Bí ìyá ṣe rí, bẹ́ẹ̀ni ọmọ rẹ̀ obìnrin.”
45. Ọmọ ìyà rẹ ni ọ lóòtọ́, to korìíra ọkọ rẹ àti àwọn ọmọ rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ara ilé àwọn arábìnrin rẹ ni ọ nitootọ, àwọn to n korìíra ọkọ wọn sílẹ̀, tó tún ń korìíra àwọn ọmọ. Ará Híítì ni ìyá rẹ, baba rẹ si jẹ́ ara Ámórì.
46. Ẹ̀gbọ́n rẹ obìnrin ni Samaríà, òun àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ n gbé ni apá aríwá rẹ, Sódómù sì ni àbúrò rẹ, obìnrin tó ń gbé pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin rẹ ni ìhà gúúsù rẹ.
47. Kì í sẹ pé ìwọ rìn ni ọ̀nà wọn nìkan, tàbí ṣe àfiwé ìwà irira wọn ṣùgbọ́n ní àárin àkókò kúkúrú díẹ̀, ìwọ bàjẹ́ jù wọ́n lọ
48. Olúwa Ọlọ́run wí pé, Bí mo ṣe wà láàyè Sódómù tí í se ẹgbọ́n rẹ obìnrin àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ kò ṣe to ohun tí ìwọ àti ọmọbìnrin rẹ ṣe.
49. “ ‘Wò ó, ẹ̀sẹ̀ tí Sódómù ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obìnrin sẹ̀ nìyìí: Òun àti àwọn ọmọbìnrin rẹ gbéraga, wọ́n jẹ́ alájẹjù àti aláìbìkítà; wọn kò ran talákà àti aláìní lọ́wọ́
50. Nítorí náà, mo mu wọn kúrò níwájú mi lójú mi gẹ́gẹ́ bi iwọ ti ròó, nítorí ìgbéraga àti àwọn Ohun ìríra tí wọ́n ṣe.