Ísíkẹ́lì 16:19-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. O tún gbé oúnjẹ tí mo fún ọ-ìyẹ̀fún dáradára, òróró àti oyin-fún wọn gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sísun olóòórùn dídùn; ohun tó ṣẹlẹ̀ nìyìí, ni Olúwa Ọlọ́run wí.

20. “ ‘Àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin tí o bí fún mi lo ti fi rúbọ bí oúnjẹ fún àwọn òrìṣà. Ṣé ìwà àgbèrè rẹ kò ha tó bí?

21. Ẹ dú àwọn ọmọ mí lọ́rùn, o fà wọ́n fún ère gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sísun,

22. Nínú gbogbo iṣẹ́ ìríra àti ìwà àgbérè rẹ, o kò rántí ìgbà èwe rẹ, nígbà tó o wà ní ìhòòhò, tó ń jàgùdù nínú ẹ̀jẹ̀.

Ísíkẹ́lì 16