2. Olúwa sì sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, àwọn ọkùnrin yìí ló ń pète ibi, wọ́n sì ń gba ìmọ̀ràn búburú kalẹ̀ nínú ìlú.
3. Wọ́n ní, ‘kò ha tí ì tó àsìkò láti kọ́lé? Ìlú yìí ni ìkòkò ìdáná, àwa sì ni ẹran’.
4. Nítorí náà sọtẹ́lẹ̀ nípa wọn; ọmọ ènìyàn, sọ tẹ́lẹ̀.”
5. Ẹ̀mí Olúwa sì bà lé mi, ó sì wí pé, “Sọ̀rọ̀!” Báyìí ni Olúwa wí, Ohun tí ẹ-ń sọ níyìí, ilé Ísírẹ́lì, mo mọ ohun tó wà lọ́kàn yín.
6. Bí ẹ ṣe ń pànìyàn tún ti pọ̀ síi nínú ìlú, òkú sì ti kún gbogbo ojú pópó.
7. “Torí náà, báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí, àwọn òkú tí ẹ pa sáàrin yín ni ẹran, ìlú yìí sì ni ìkòkò ìdáná ṣùgbọ́n n ó le yín jáde níbẹ̀.
8. Ẹ bẹ̀rù idà, n ó sì mú idà wá sórí yín, bẹ́ẹ̀ ni Olúwa wí.