1. Mo sì wò ó, mo rí ohun kan tó dàbí òkúta sáfírè nínú òfuurufú tó wà lókè orí kérúbù, ìrísí ohun yìí sì dàbí ìtẹ́.
2. Olúwa sì sọ fún ọkùnrin tó wọ aṣọ funfun pé, “Lọ sí àárin àwọn kẹ̀kẹ́ tó wà lábẹ́ kérúbù. Bu ẹyin iná tó kúnwọ́ rẹ láàrin kérúbù, kí o sì fọ́n-ọn sórí ìlú náà.” Ó sì lọ lóju mi.
3. Àwọn kérúbù dúró sí apá gúúsù tẹ́ḿpìlì nígbà tí ọkùnrin náà wọlé, ìkùukùu sì bo inú àgbàlá.
4. Ògo Olúwa sì kúrò lórí àwọn kérúbù, ó bọ́ sí ibi ìloro tẹ́ḿpìlì. Ìkùukùu sì bo inú tẹ́ḿpìlì, àgbàlá sì kún fún ìmọ́lẹ̀ àti ògo Olúwa.
5. A sì gbọ́ ariwo ìyẹ́ àwọn kérúbù yìí títí dé àgbàlá tó wà níta gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí Ọlọ́run Olódùmáre bá ń sọ̀rọ̀.
6. Nígbà tí Olúwa pàṣẹ fún ọkùnrin aláṣọ funfun yìí pé, “Mú iná láàrin àwọn kẹ̀kẹ́, láàrin àwọn kérúbù,” ó sì lọ dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn kẹ̀kẹ́ náà.
7. Ọ̀kan nínú àwọn kérúbù sì nawọ́ síbi iná tó wà láàrin kérúbù yóòkù. Ó mú lára rẹ, ó fi sínú ọwọ́ ọkùnrin aláṣọ funfun, òun náà gbàá, ó sì jáde lọ.
8. (Ohun tó dàbí ọwọ́ ènìyàn wà lábẹ́ ìyẹ́ àwọn kérúbù yìí).