Ìfihàn 9:5-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. A sì pàṣẹ fún wọn pé, kí wọn má ṣe pa wọ́n, ṣùgbọ́n kí a dá wọn ni oró ni oṣù marùn-ún: oró wọn sì dàbí oró àkéekèe, nígbà tí o bá ta ènìyàn.

6. Ní ọjọ́ wọ̀nyí ni àwọn ènìyàn yóò sì máa wá ikú, wọn kì yóò sì rí i; wọn yóò sì fẹ́ láti kú, ikú yóò sì sá kúrò lọ́dọ̀ wọn.

7. Ìrísí àwọn eṣú náà sì dàbí àwọn ẹṣin tí a múra sílẹ̀ fún ogun; àti ní orí wọn ni ohun tí o dàbí àwọn adé wúrà wà, ojú wọn sì dàbí ojú ènìyàn;

8. Wọn sì ní irun bí obìnrin, ehín wọn sì dàbí ti kìnìún.

9. Wọn sì ní ìgbàyà tí ó dàbí ìgbàyà irin; ìró ìyẹ́ wọn sì dàbí ìró kẹ̀kẹ́ ẹsin púpọ̀ tí ń súré lọ sí ogun.

10. Wọ́n sì ni ìrù àti oró bí tí àkéekèe, àti ní ìrù wọn ni agbára wọn wà láti pa ènìyàn lára fún oṣù márùn-ún.

11. Wọ́n ní ańgẹ́lì ọ̀gbun náà bí ọba lórí wọn, orúkọ rẹ̀ ní èdè Hébérù ní Ábádónì, àti ni èdè Gíríkì orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Àpólíónì.

12. Ègbé kan tí kọjá, kíyèsi i, ègbé méjì ń bọ̀ síbẹ̀ lẹ́yìn èyí.

Ìfihàn 9