Ìfihàn 13:14-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Ó sì ń tán àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé jẹ nípa àwọn ohun ìyanu tí a fí fún un láti ṣe níwájú ẹranko náà; ó ń wí fún àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé láti yá àwòrán fún ẹranko náà; ó ń wí fún àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé láti yá àwòrán fún ẹranko náà tí o tí gbá ọgbẹ́ idà, tí ó sì yè.

15. A sì fi fún un, láti fi ẹ̀mí fún àwòrán ẹranko náà kí ó máa sọ̀rọ̀ kí ó sì mu kí a pa gbogbo àwọn tí kò foríbalẹ̀ fún àwòrán ẹranko náà.

16. Ó sì mu gbogbo wọn, àti kékeré àti ńlá, ọlọ́rọ̀ àti talákà, olómìnira àti ẹrú, láti gba àmì kan sí ọwọ́ ọ̀tún wọn, tàbí ní iwájú orí wọn;

17. Àti kí ẹnikẹ́ni má lè rà tàbí tà, bí kò ṣe ẹni tí o bá ní àmì náà, èyí ni orúkọ ẹranko náà, tàbí àmì orúkọ rẹ̀

18. Niyìn ni ọgbọ́n gbé wà. Ẹni tí o bá ní òye, kí o ka nọ́ḿbà tí ń bẹ̀ lára ẹranko náà: nítorí pé nọ́ḿbà ènìyàn ni, nọ́ḿbà rẹ̀ náà sì jẹ́ ẹgbẹ̀ta ọgọ́ta ẹẹ́fà. (666).

Ìfihàn 13