5. Ó sì bi ọmọkùnrin kan tí yóò fi ọ̀pá irin ṣe àkóso gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè: a sì gba ọmọ rẹ̀ lọ sókè sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, àti sí orí ìtẹ́ rẹ̀.
6. Obìnrin náà sì sá lọ sí ihà, níbi tí a gbé ti pèṣè ààyè sílẹ̀ dè é láti ọwọ́ Ọlọ́run wá, pé kí wọ́n máa bọ́ ọ níbẹ̀ ní ẹgbẹ̀fà ọjọ́ ó-lé-ọgọ́ta.
7. Ogun sì ń bẹ ní ọ̀run: Mákẹ́lì àti àwọn ańgẹ́lì rẹ̀ bá dírágónì náà jagun; dírágónì sì jagun àti àwọn angẹ́lì rẹ̀.
8. Wọ́n kò sì lè ṣẹ́gun; Bẹ́ẹ̀ ni a kò sì rí ipò wọn mọ́ ni ọ̀run.
9. A sì lé dírágónì ńlá náà jáde, ejò láéláé ni, tí a ń pè ni Èṣù, àti Sàtanì, tí ń tan gbogbo ayé jẹ: a sì lé e jù sí ilẹ̀ ayé, a sì lé àwọn ańgẹ́lì rẹ̀ jáde pẹ̀lú rẹ̀.
10. Mo sì gbọ́ ohùn rara ní ọ̀run, wí pè:“Nígbà yìí ni ìgbàlà dé, àti agbára, àti ìjọba Ọlọ́run wá,àti ọlá àti Kírísítì rẹ̀.Nítorí a tí le olùfisùn àwọn arakùnrin wa jáde,tí o ń fí wọ́n sùn níwájú Ọlọ́run wa lọ́sàn-án àti lóru.
11. Wọ́n sì ti ṣẹ́gun rẹ̀nítorí ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́-Àgùntàn náà,àti nítorí ọ̀rọ̀ ẹ̀rí wọn,wọn kò sì fẹ́ràn ẹ̀míwọn àní títí dé ikú.
12. Nítorí náà ẹ máa yọ̀, ẹ̀yin ọ̀run,àti ẹ̀yin tí ń gbé inú wọn.Ègbé ni fún ayé àti òkun;nítorí Èṣù sọ̀kalẹ̀ tọ̀ yín wá ní ìbínú ńlá,nítorí ó mọ̀ pé ìgbà kúkúrú ṣá ni òun ní.”