Ìṣe Àwọn Àpósítélì 9:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ṣùgbọ́n síbẹ̀, Ṣọ́ọ̀lù sí ń tẹ̀síwájú nínú mímí-èémí ìhalẹ̀-mọ́ni àti ìpani sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Olúwa. Ó tọ olórí alúfà lọ,

2. ó bèèrè ìwé lọ́wọ́ rẹ̀ sí sínágọ́gù tí ń bẹ ní ìlú Dámásíkù pé, bí òun bá rí ẹnikẹ́ni tí ń bẹ ni Ọ̀nà yìí, ìbaà ṣe ọkùnrin, tàbí obìnrin, kí òun lè mú wọn ní dídè wá sí Jerúsálémù.

3. Ó sì ṣe, bí ó ti ń lọ, ó sì súmọ́ Dámásíkù; lójijì, ìmọ́lẹ̀ láti ọ̀run wá mọlẹ̀ yí i ká.

4. Ó sì subú lulẹ̀, ó gbọ́ ohùn tí ó ń fọ̀ sí i pé, “Ṣọ́ọ̀lù, Ṣọ́ọ̀lù, è é ṣe ti ìwọ fi ń ṣe inúnibíni sí mi?”

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 9