Ìṣe Àwọn Àpósítélì 4:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Bí wọn sì tí ń bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀, àwọn àlùfáà àti olórí ẹ̀sọ́ tẹ́ḿpílì àti àwọn Sádúsì dìde sí wọn.

2. Inú bí wọn, nítorí tí wọn kọ́ àwọn ènìyàn, wọ́n sì ń wàsúù àjíǹde kúrò nínú òkú nínú Jésù.

3. Wọn sì náwọ́ mú wọn, wọn sì tì wọ́n mọ́ ilé túbú títí ó fi dí ijọ́ kejì; nítorí tí alẹ́ ti lẹ́ tan.

4. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà gbàgbọ́; iye àwọn ọkùnrin náà sì tó ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (5000).

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 4