14. Bí wọ́n sì tí wà níbẹ̀ lọ́jọ́ púpọ̀, Fẹ́sítúsì mú ọ̀ràn Pọ́ọ̀lù wá síwájú ọba, wí pé, “Fẹ́líkísì fi ọkùnrin kan ṣílẹ̀ nínú túbú.
15. Ẹni tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbààgbà àwọn Júù fi sùn nígbà tí mo wà ni Jerúsálémù, wọ́n ń fẹ́ kí èmi ó dá a lẹ́bi ikú.
16. “Àwọn ẹni tí mo sì dá lóhùn pé, kì í ṣe àṣà àwọn ará Róòmù láti dá ẹnìkẹ́ni lẹ́bí, kí ẹni tí a fiṣùn náà tó ko àwọn olùfisùn rẹ̀ lójú, láti lè ri àyè wí tí ẹnu rẹ̀, nítorí ọ̀ràn tí a kà sí i lọ́rùn,
17. Nítorí náà nígbà tí wọ́n jùmọ̀ wá sí ìhín yìí, èmi kò fi ọ̀rọ̀ náà falẹ̀ rara, níjọ́ kéjì mo jókòó lórí ìtẹ́ ìdájọ́, mo sì pàṣẹ pé kí a mú ọkùnrin náà wá.
18. Nígbà tí àwọn olùfiṣùn náa dìde, wọn kò ka ọ̀ràn búburú irú èyí tí mo rò sí i lọ́rùn.
19. Ṣùgbọ́n wọ́n ní ọ̀ràn kan sí i, ní ti ìsìn wọn, àti ní ti Jésù kan tí o tí kú, tí Pọ́ọ̀lù tẹnumọ́ pé ó wà láàyè.
20. Bí èmi kò sì tí mọ̀ bí a tí ń se ìwàdìí nǹkan wọ̀nyí, mo bí i lere pé ṣe ó ń fẹ́ lọ sì Jerúsálémù, kí a sì ṣe ẹjọ́ nǹkan wọ̀nyí níbẹ̀.
21. Ṣùgbọ̀n nígbà tí Pọ́ọ̀lù fi ọ̀ràn rẹ lọ Ọ̀gọ́sítù, pé kí a pa òun mọ́ fún ìdájọ́ rẹ̀, mo pàṣẹ pé kí a pa á mọ́ títí èmi o fi lè rán an lọ sọ́dọ̀ Késárì.”
22. Àgírípà sí wí fún Fésítúsì pé, “Èmi pẹ̀lú fẹ́ láti gbọ ọ̀rọ̀ ọkùnrin náà tìkááramì,” Ó sì wí pé, “Ní ọ̀la ìwọ ó gbọ́ ọ.”