Ìṣe Àwọn Àpósítélì 23:25-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

25. Ó sì kọ ìwé kan báyìí pé:

26. Kíláúdíù Lísíà,Sí Fẹ́líkísì baálẹ̀ ọlọ́lá jùlọ:Àlàáfíà.

27. Àwọn Júù mú ọkùnrin yìí, wọ́n sì ń pète láti pa á: nígbà náà ni mo dé pẹ̀lú ogun, mo sì gbà á lọ́wọ́ wọn nígbà tí mo gbọ́ pé ará Róòmù ni í ṣe.

28. Nígbà tí mo sì ń fẹ́ mọ ìdí ọ̀ràn tí wọn fi ẹ̀sùn kàn án sí, mo mú un sọ̀kalẹ̀ lọ sí àjọ ìgbìmọ̀ wọn.

29. Ẹni tí mo rí pé, wọ́n fisùn nítorí ọ̀ràn òfin wọn, bẹ́ẹ̀ ni kò dá ọ̀ràn ohun kan tí ó tọ́ sí ikú àti sí ẹ̀wọ̀n.

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 23