14. “Nígbà náà ni ó wí pé: ‘Ọlọ́run àwọn baba wa ti yàn ọ́ láti mọ ìfẹ́ rẹ̀, àti láti ri Ẹni Òdodo náà, àti láti gbọ́ ọ̀rọ̀ láti ẹnu rẹ̀.
15. Ìwọ yóò jẹ́ ẹlẹ́rìí rẹ̀ fún gbogbo ènìyàn, nínú ohun tí ìwọ tí rí tí ìwọ sì ti gbọ́.
16. Ǹjẹ́ nísinsìn yìí, kín ni ìwọ ń dúró dè? Dìde, kí a sì bamitíìsì rẹ̀, kí ó sì wẹ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ nù, kí ó sì máa pé orúkọ rẹ̀.’
17. “Nígbà tí mo padà wá sí Jerúsálémù tí mo ǹ gbàdúrà ní tẹ́ḿpílì, mo bọ́ sí ojúran,
18. mo sì rí Olúwa, ó ń sọ̀rọ̀ fún mi pé, ‘Kíá! Jáde kúrò ní Jerúsálémù kán-kán, nítorí wọn kì yóò gba ẹ̀rí rẹ nípa mi gbọ́.’
19. “Èmi sì wí pé, ‘Olúwa, àwọn ènìyàn wọ̀nyí pàápàá mọ̀ pé èmi ti lọ láti inú sínágọ́gù kan sí èkejì láti máa sọ wọ́n sínú túbú àti láti máa lu àwọn tí ó gbà ọ́ gbọ́.
20. Nígbà tí a sì ta ẹ̀jẹ̀ Sítéfánù ẹlẹ́ríì rẹ sílẹ̀, èmi náà pẹ̀lú dúró níbẹ̀, mo sì ní ohùn sí ikú rẹ̀, mo sì ń se ìtọ́jú aṣọ àwọn ẹni tí ó pa á.’
21. “Nígbà náà ni Olúwa wí fún mi pé, ‘Máa lọ: nítorí èmi ó rán ọ sí àwọn aláìkọlà lókèèrè réré.’ ”
22. Wọ́n sì fi etí sí ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù títí tí ó fi sọ ọ̀rọ̀ yìí. Nígbà yìí ni wọ́n gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì kígbe wí pé, “Ẹ mu ẹni yìí kúrò láyé! Kò yẹ kí ó wà láàyè!”
23. Bí wọ́n sì ti ń kígbe, tí wọ́n sì ń jú aṣọ wọn káàkiri, tí wọ́n ń ku eruku sí ojú ọ̀run,
24. olórí ogun pàṣẹ pé kí a mú Pọ́ọ̀lù wá sínú àgọ́ àwọn ológun. Ó sì pàṣẹ kí wọ́n ó lù ú, kí wọn fi ọ̀rọ̀ wa lẹ́nu wò, kí òun baà lè mọ ìdí tí wọ́n fi ń kígbe lé e lórí bẹ́ẹ̀.
25. Bí wọ́n sí tí fi okùn-ọṣán dè é, Pọ́ọ̀lù bí balógun ọ̀rún tí ó dúró tì í pé, “Ó ha tọ́ fún yín láti na ẹni tí i ṣe ará Róòmù ni àìdálẹ́bi bí?”
26. Nígbà tí balógun ọ̀rún sì gbọ́ èyí, ó lọ wí fún olórí-ogun pé, “Kín ni ó fẹ́ ṣe yìí: nítorí ọkùnrin yìí ará Róòmù ní i ṣe?”
27. Olórí-ogun sì dé, ó sì bí Pọ́ọ̀lù pé, “Sọ fún mi, ará Róòmù ni ìwọ jẹ́ bí?”Ó sì wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni.”
28. Olórí-Ogun sì dáhùn wí pé, “Owó púpọ̀ ni mo fi ra ọlá ìbílẹ̀ yìí.”Pọ́ọ̀lù wí pé, “Ṣùgbọn a bí mi sínú rẹ̀ ni.”