Ìṣe Àwọn Àpósítélì 18:25-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

25. Ọkùnrin yìí ni a tí kọ́ ní ọ̀nà tí Olúwa; ó sì ṣe ẹni tí ó ní ìtara tí ẹ̀mí, ó ń sọ̀rọ̀ ó sì ń kọ́ni ní àwọn ohun tí i ṣe ti Olúwa dáradára; kìkì bamitíìsímù tí Jòhánù ní ó mọ̀.

26. Ó sì bẹ̀rẹ̀ ṣí fi ìgboyà sọ̀rọ̀ ni Sínágọ́gù: nígbà tí Àkúílà àti Pìrìskílà gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n mú un sọ́dọ̀ wọ́n sì túbọ̀ sọ ọ̀nà Ọlọ́run fún un dájúdájú.

27. Nígbà tí ó sì ń fẹ́ kọjá lọ sì Ákáyà, àwọn arakùnrin gbà á ní ìyànjú, wọ́n sì kọ̀wé sí àwọn ọmọ-ẹ̀hìn kí wọ́n gbà á: nígbà tí ó sì dé, ó ràn àwọn tí ó gbàgbọ́ nípasẹ̀ oore-ọfẹ lọ́wọ́ púpọ̀,

28. Nítorí tí o sọ àsọyé fún àwọn Júù ní gbangba, ó ń fi í hàn nínú ìwé-mímọ́ pé, Jésù ni Kíríṣítí.

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 18