Ìṣe Àwọn Àpósítélì 16:37-40 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

37. Ṣùgbọ́n Pọ́ọ̀lù wí fún wọn pé, “Wọ́n lù wá ni gbangba, wọ́n sì sọ wá sínú túbú ni àìjẹ̀bí, àwa ẹni tí ì ṣe ara Róòmù: ṣe nísinsìnyìí wọ́n fẹ́ tì wá jáde nikọ̀kọ̀? Àgbẹdọ̀! Ṣùgbọ́n kí àwọn tìkara wọn wá mú wa jáde!”

38. Àwọn ọlọ́pàá sì sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún àwọn onídàjọ́: ẹ̀rù sì bà wọ́n, nígbà tí wọ́n gbọ́ pé ará Róòmù ni wọ́n.

39. Wọ́n sì wá, wọ́n sìpẹ̀ fún wọ́n, wọn sì mú wọn jáde, wọ́n sì bẹ̀ wọ́n pé, ki wọn jáde kúrò ni ìlú náà.

40. Wọ́n sì jáde nínú túbú, wọ́n sì wọ ilé Lídíà lọ: nígbà tí wọn sì tí rí àwọn arákùnrin, wọ́n tù wọ́n nínú, wọn sì jáde kúrò.

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 16