19. “Ǹjẹ́ ìmọ̀ràn tèmi ni pé, kí a máa ṣe yọ àwọn ti aláìkọlà ti ó yípadà sí Ọlọ́run lẹ́nu.
20. Ṣùgbọ́n kí a kọ̀wé si wọn, kí wọ́n fà sẹ̀hín kúrò nínú èérí òrìṣà, àti kúrò nínú àgbèrè, àti nínú ẹ̀jẹ̀.
21. Mósè nígbà àtijọ́, sá ní àwọn ti ń wàásù rẹ̀, ni ìlú gbogbo, a máa ń kà á nínú sínágọ́gù ni ọjọ́jọ́ ìsinmi.”
22. Nígbà nàá ni ó tọ́ lójú àwọn àpósítélì, àti àwọn alàgbà pẹ̀lú gbogbo ìjọ, láti yan ènìyàn nínú wọn, àti láti rán wọ́n lọ sí Áńtíókù pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù àti Bánábà: Júdà ti a ń pè àpèlé rẹ̀ ní Básábà, àti Sílà, ẹni tí ó lórúkọ nínú àwọn arákùnrin.