Ìṣe Àwọn Àpósítélì 11:28-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

28. Nígbà tí ọ̀kan nínú wọn, ti a ń pè ni Ágábù sí dìde, ó ti ipa Ẹ̀mí sọ pé, ìyàn ńlá yóò mú yíká gbogbo ilẹ̀ Róòmù. (Èyí sì ṣẹlẹ̀ nígbà ìsèjọba Kíláúdíù.)

29. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì pinnu, olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí agbára rẹ̀ ti tó, láti rán ìrànlọ́wọ́ sí àwọn arakùnrin tí ó wà ní Jùdíà.

30. Wọn sì ṣe bẹ́ẹ̀, wọn sì fi i ránṣẹ́ sí àwọn àgbà láti ọwọ́ Bánábà àti Ṣọ́ọ̀lù.

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 11