Ìṣe Àwọn Àpósítélì 11:26-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

26. nígbà tí ó sì rí i, ó mú un wá sí Áńtíókù. Fún ọdún kan gbáko ni wọ́n fi ń bá ìjọ péjọ pọ̀, tí wọ́n sì kọ́ ènìyàn púpọ̀. Ní Áńtíókù ni a sì kọ́kọ́ ti pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ni “Kírísítìánì.”

27. Ní ọjọ́ wọ̀nyí ni àwọn wòlíì sì ti Jerúsálémù sọ̀kalẹ̀ wá sí Áńtíókù.

28. Nígbà tí ọ̀kan nínú wọn, ti a ń pè ni Ágábù sí dìde, ó ti ipa Ẹ̀mí sọ pé, ìyàn ńlá yóò mú yíká gbogbo ilẹ̀ Róòmù. (Èyí sì ṣẹlẹ̀ nígbà ìsèjọba Kíláúdíù.)

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 11