1. Éfúráímù ń jẹ afẹ́fẹ́;Ó n lépa afẹ́fẹ́ ìwọ̀ oòrùn ní gbogbo ọjọ́.Ó sì ń gbèrú nínú irọ́Ó dá májẹ̀mú pẹ̀lú ÁsíríàÓ si fi òróró ólífì ránsẹ́ sí Éjíbítì.
2. Olúwa ní ẹ̀sùn tí yóò fí kan Júdàyóò fìyà jẹ Jákọ́bù gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ̀yóò sì sán fún-un gẹ́gẹ́ bí i ìṣe rẹ̀.
3. Láti inú oyun ni ó ti di arákùnrin rẹ̀ mú ni gìgísẹ̀,àti nípa ìpá rẹ̀ ó ni agbára pẹ̀lú Ọlọ́run
4. Ó bá ángẹ́lì ja ìjàkadì, ó sì borí rẹ̀Ó sunkún, ó sì bẹ̀bẹ̀ fún ojú rere rẹ̀Ó bá Olúwa ní Bẹ́tẹ́lìÓ sì bá a sọ̀rọ̀ níbẹ̀,
5. àní Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun; Olúwa ni orúkọ ìrántí rẹ̀