Hágáì 2:14-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Nígbà náà ni Hágáì dáhùn ó sì wí pé, “ ‘Bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn wọ̀nyí rí, bẹ́ẹ̀ sì ni orílẹ̀-èdè yìí rí níwájú mi,’ ni Olúwa wí. ‘Bẹ́ẹ̀ sì ni olukuluku iṣẹ́ ọwọ́ wọn; èyí tí wọ́n sì fi rúbọ níbẹ̀ jẹ́ aláìmọ́.

15. “ ‘Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ẹ ro èyí dáradára láti òní yìí lọ, ẹ kíyèsí bí nǹkan ṣe rí tẹ́lẹ̀, a to òkúta kan lé orí èkejì ní tẹ́ḿpìlì Olúwa.

16. Nígbà tí ẹnikẹ́ni bá dé ibi ìlé ogún, mẹ́wàá péré ni. Nígbà tí ẹnikẹ́ni bá dé ibi ìfúntí wáìnì láti wọn àádọ́ta ìwọ̀n, ogún péré ni.

17. Mo fi ìrẹ̀dànù, ìmúwòdú àti yìnyín bá gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ yín jà; síbẹ̀ ẹ̀yin kò yípadà sí ọ̀dọ̀ mi,’ ni Olúwa wí.

18. ‘Láti òní lọ, láti ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹ́sàn-án, yìí kí ẹ kíyèsí, kí ẹ sì rò ó dáradára, ọjọ́ ti a fi ìpìlẹ̀ tẹ́ḿpìlì Olúwa lé lẹ̀, ròó dáradára:

19. Ǹjẹ́ èso ha wà nínú abà bí? Títí di àkókò yìí, àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ àti pómégíránátè, àti igi ólífì kò ì tíì so èso kankan.“ ‘Láti òní lọ ni èmi yóò bùkún fún-un yin.’ ”

20. Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tún tọ Hágáì wá nígbà kejì, ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù náà pé:

21. “Sọ fún Sérúbábélì baálẹ̀ Júdà pé èmi yóò mi àwọn ọ̀run àti ayé.

22. Èmi yóò bi ìtẹ́ àwọn ìjọba ṣubú, Èmi yóò sì pa agbára àwọn aláìkọlà run; Èmi yóò sì dojú àwọn kẹ̀kẹ́ ogun dé, àti àwọn tí ń gùn wọ́n; ẹṣin àti àwọn ẹlẹ́sin yóò ṣubú; olúkúlùkù nípa idà arákùnrin rẹ̀.”

23. Olúwa àwọn wí pé, “Ní ọjọ́ náà, àwọn ọmọ-ogun iwọ ìránṣẹ́ mi Sérúbábélì ọmọ Séítíélì, Èmi yóò mú ọ, Èmi yóò sì sọ ọ di bí òrùka èdìdì mi, nítorí mo ti yan ọ, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.”

Hágáì 2