1. Ǹjẹ́ ohun tí mo ń wí ni pé, níwọ̀n ìgbà tí àrólé náà bá wà ní èwe, kò yàtọ̀ nínú ohunkóhun sí ẹrú bí ó tilẹ̀ jẹ́ Olúwa ohun gbogbo.
2. Ṣùgbọ́n ó wà lábẹ́ olùtọ́jú àti ìríjú títí àkókò tí baba ti yàn tẹ́lẹ̀.
3. Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ sì ni àwa, nígbà tí àwa wà ní èwe, àwa wà nínú ìdè lábẹ́ ìpilẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀dá.
4. Ṣùgbọ́n nígbà tí àkókò kíkún náà dé, Ọlọ́run rán ọmọ rẹ̀ jáde wá, ẹni tí a bí nínú obìnrin tí a bí lábẹ́ òfin.
5. Láti ra àwọn tí ń bẹ lábẹ́ òfin padà, kí àwa lè gba ìsọdọmọ,
6. Àti nítorí tí ẹ̀yin jẹ́ ọmọ, Ọlọ́run sì ti rán Ẹ̀mí Ọmọ rẹ̀ wá sínú ọkàn yín, tí ń ké pé, “Ábà, Baba.”
7. Nítorí náà ìwọ kì í ṣe ẹrú, bí kò ṣe ọmọ; àti bí ìwọ bá ń ṣe ọmọ, ǹjẹ́ ìwọ di àrólé Ọlọ́run nípaṣẹ̀ Kírísítì.
8. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, nígbà tí ẹ̀yin kò tí i mọ Ọlọ́run, ẹ̀yin ti sìnrú fún àwọn tí kì í ṣe Ọlọ́run nípa ẹ̀dá.
9. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, nígbà tí ẹ̀yin ti mọ Ọlọ́run tan tàbí kí a ṣá kúkú wí pé ẹ di mímọ́ fún Ọlọ́run, è é ha ti rí tí ẹ tún fi yípadà sí aláìlera àti alágbe ìpìlẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀dá, lábẹ́ èyí tí ẹ̀yin tún fẹ́ padà wá sìnrú?
10. Ẹ̀yin ń kíyèsí ọjọ́ àti àkókò, àti ọdún.
11. Ẹ̀rù yin ń bà mí, kí o má bà ṣe pé lásán ni mo ṣe làálàá lórí yín.
12. Ará, mo bẹ̀ yín, ẹ dà bí èmi: nítorí èmi dà bí ẹ̀yin: èyin kò ṣe mí ní ibi kan.
13. Ẹ̀yin mọ̀ pé nínú àìlera ni mo wàásù ìhìnrere fún yín ní àkọ́kọ́.
14. Èyí tí ó sì jẹ́ ìdánwò fún yín ní ara mi ni ẹ kò kẹ́gàn, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò sì kọ̀; ṣùgbọ́n ẹ̀yin gbà mí bí áńgẹ́lì Ọlọ́run, àní bí Kírísítì Jésù.
15. Ǹjẹ́ ayọ̀ yín ìgbà náà há dà? Nítorí mo gba ẹ̀rí yín pé, ìbá ṣe é ṣe, ẹ̀ ò bá yọ ojú yín jáde, ẹ̀ bá sì fi wọ́n fún mi.
16. Ǹjẹ́ mo há di ọ̀ta yín nítorí mo sọ òtítọ́ fún yín bí?
17. Wọ́n ń fi ìtara wá yin, ṣùgbọ́n kì í ṣe fún rere; wọ́n ń fẹ́ já yin kúrò, kí ẹ̀yin lè máa wá wọn.