13. Ṣíwájú síi, ọba gbọdọ̀ mọ̀ pé tí a bá kọ́ ìlú yìí àti tí a sì tún àwọn ògiri rẹ̀ mọ, kò sí owó orí, owó òde tàbí owó ibodè tí a ó san, owó tí ó sì ń wọlé fún ọba yóò sì dínkù.
14. Nísinsìn yìí níwọ̀n ìgbà tí a ní ojúṣe sí ààfin ọba, kò sì bójúmu fún wa láti rí ìtàbùkù ọba, àwa ń rán iṣẹ́ yìí láti sọ fún ọba,
15. kí a bá a lè ṣe ìwádìí ní inú ìwé ìrántí àwọn àṣíwájú rẹ̀. Nínú ìwé ìrántí wọn yìí, ìwọ yóò ríi wí pé, ìlú yìí jẹ́ ìlú aṣọ̀tẹ̀, oní wàhálà sí àwọn ọba àti àwọn ìgbèríko, ibi ìṣọ̀tẹ̀ láti ìgbà àtijọ́. Ìdí ni èyí tí a ṣe pa ìlú yìí run.
16. A fi dá ọba lójú wí pé tí a bá tún ìlú kọ́ àti ti àwọn ògiri rẹ̀ si di mímọ padà, kì yóò sì ohun ti yóò kù ọ́ kù ní agbégbé Yúfúrátè.
17. Ọba fi èsì yìí ránṣẹ́ padà:Sí Réhúmì balógun, Ṣímíṣáì akọ̀wé àti àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn yóòkù tí ń gbé ní Samáríà àti ní òpópónà Yúfúrátè:Ìkíní.
18. A ti ka ìwé tí ẹ fi ránṣẹ́ sí wa, a sì ti túmọ̀ rẹ̀ níwájú mi.
19. Mo pa àṣẹ, a sì ṣe ìwádìí, nínú ìtàn ọjọ́ pípẹ́ àti ti ìsinsinyìí ti ìṣọ̀tẹ̀ sí àwọn ọba pẹ̀lú, ó sì jẹ́ ibi ìṣọ̀tẹ̀ àti ìrúkèrúdò.
20. Jérúsálẹ́mù ti ní àwọn ọba alágbára tí ń jọba lórí gbogbo àwọn agbégbé Yúfúrátè, àti àwọn owó orí, owó òde àti owó ibodè sì ni wọ́n ń san fún wọn.
21. Nísinsìn yìí pa àṣẹ fún àwọn ọkùnrin yìí láti dá iṣẹ́ dúró, kí a má ṣe tún ìlú náà kọ títí èmi yóò fi pàṣẹ.
22. Ẹ ṣọ́ra kí ẹ má ṣe àìkọbi-ara sí ọ̀rọ̀ yìí. Èéṣe tí ìbàjẹ́ yóò fi pọ̀ sí i, sí ìpalára àwọn ọba?
23. Ní kété tí a ka ẹ̀dà ìwé ọba Aritaṣéṣéṣì sí Réhúmì àti Ṣímíṣáì akọ̀wé àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn, wọ́n yára lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn Júù ní Jérúsálẹ́mù pẹ̀lú, wọ́n fi agbára mú wọn láti dáwọ́ dúró.
24. Báyìí, iṣẹ́ lórí ilé Ọlọ́run ní Jérúsálẹ́mù wá sí ìdúró jẹ́ẹ́ títí di ọdún kejì ìjọba Dáríúsì ọba Páṣíà.