14. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, èmi yóò rán ìdààmú ti ó ní agbára gidigidi sí ọ, sí àwọn ìjòyè rẹ àti sí àwọn ènìyàn rẹ, kí ìwọ kí ó lè mọ̀ pé, kò sí ẹni bí èmi ni gbogbo ayé.
15. Ó ti yẹ kí n ti na ọwọ́ mi jáde láti kọ lù ọ́ àti àwọn ènìyàn rẹ pẹ̀lú ohun búburú ti kò bá ti run yín kúrò ni orí ilẹ̀.
16. Ṣùgbọ́n nítorí èyí ni mo ṣe dá ọ sí, kí èmi kí ó lè fi agbára mi hàn ọ́, kí a bá à lè gbọ́ òkìkí orúkọ mi ní gbogbo ayé.
17. Ṣíbẹ̀ ìwọ tún gbógun ti àwọn ènìyàn mi, ìwọ kò sì jẹ́ kí wọn lọ.
18. Nítorí náà, ni ìwòyí ọ̀la, èmi yóò rán òjò o yìnyín tí irú rẹ̀ kò tí i rọ̀ rí ni Éjíbítì láti ìpìlẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ títí di àkókò yìí.
19. Pàṣẹ nísin yìí láti kó ẹran-ọ̀sìn yin àti ohun gbogbo ti ẹ ni ní pápá wá sí abẹ́ ààbò, nítorí òjò yìnyín yóò rọ̀ sí orí àwọn ènìyàn àti ẹran ti a kò kó wá sí abẹ́ ààbò tí wọ́n sì wà ni orí pápá, wọn yóò sì kú.’ ”
20. Àwọn ti ó bẹ̀rù ọ̀rọ̀ Olúwa lára àwọn ìjòyè Fáráò yára lọ láti kó àwọn ẹrú àti àwọn ẹran-ọ̀sìn wọn wá sí abẹ́ ààbò.