4. Ó sì tún ṣe òpó igi kaṣíà, ó sì bò wọ́n pẹ̀lú wúrà.
5. Ó sì kó àwọn òpó náà sínú òrùka ní ìhà àpótí náà láti máa fi gbé e.
6. Ó se ìbòrí àánú kìkì wúrà ìgbọ̀nwọ́ méjì àti ààbọ̀ gígùn rẹ̀ àti ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ni fífẹ̀ rẹ̀.
7. Ó sì se kérúbù méjì láti inú òlù wúrà ní òpin ìbòrí náà.
8. Ó se kérúbù kan ni òpin èkínní, ó sì tún ṣe kérúbù kejì sí èkejì; ní òpin méjèèjì ó ṣe ìtẹ́ àánú ìbòrí wọn.
9. Àwọn kérúbù sì na ìyẹ́ apá wọn sókè sí i, ó fi ìji bo ìbòrí wọn. Àwọn kérúbù kọjú sí ara wọn, wọ́n ń wo ìbòrí náà.
10. Ó se tábìlì igi kaṣíá ìgbọ̀nwọ́ méjì ní gígùn, ìgbọ̀nwọ́ kan ní fífẹ̀, àti ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ní gíga.
11. Ó sì fi kìkì wúrà bòó, ó sì se ìgbátí yí i ká.
12. Ó sì tún ṣe etí ìbù ọwọ́ fífẹ̀ yìí ká, ó sì fi ìgbátí wúrà yí etí rẹ̀ ká.
13. Ó sì dá òrùka wúrà fún tábìlì náà, ó sì so wọ́n mọ́ igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, níbi tí ẹṣẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wà.
14. Àwọn òrùka náà wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ etí rẹ̀ láti gbá àwọn òpó náà mu láti máa fi gbé tábìlì náà.
15. Igi kaṣíá ni ó fi se òpó ti a fi ń gbé tábìlì náà, ó sì fi wúrà bò ó.