Ékísódù 36:11-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Wọ́n sì pa ajábó aṣọ aláró ní etí aṣọ títa kan láti ìsẹ́tí rẹ̀ dé ibi òpin, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ní o ṣe sí ìhà etí ikangun aṣọ títa kejì ní ibi òpin èkejì.

12. Àádọ́ta (50) ajábó ní ó pa lára aṣọ títa kan, àti àádọ́ta ajábó ni ó sì lò pa ní etí aṣọ títa tí ó wà ní ọ̀kánkán ara wọn.

13. Wọ́n sì ṣe àádọ́ta ìkọ́ wúrà, ó sì lò wọ́n láti fi kọ́ méjì aṣọ títa papọ̀ bẹ́ẹ̀ Àgọ́ náà sì di ọ̀kan.

14. Wọ́n ṣe aṣọ títa ti irun ewúrẹ́ fún Àgọ́ náà lórí Àgọ́ náà mọ́kànlá ni gbogbo rẹ̀ papọ̀.

Ékísódù 36